Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti lè mọ̀ láti inú ilé ìtàwé mi, mo ti kọ nnkan bí àádọ́ta ìwé àkàgbádùn,
ṣùgbọ́n èdè Gẹẹsì ni gbogbo wọn. Ṣùgbọ́n, mo ti jẹ́ kí wọ́n túmọ̀ wọn sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èdè, àtòkọ gbogbo àwọn ìwé mi ní èdè Yoruba yóò sì wà ní ojú ewé yìí.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ kò níí pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ ó ríi pé iye àwọn ìwé tí a túmọ̀ npọ̀ síi díẹ̀díẹ̀. Nítorí náà, ẹ tún máa padà yẹ ibí yìí wò láti wádìí nípa ohun tí ó ti yí padà. Tí ẹ bá ní́i lọ́kàn pé irú ìwé kan ni ó yẹ kí ó kàn, ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí nmọ̀; èmi yóò sì sa ipá mi.
Ẹ̀wẹ̀, àwọn tí ó ti wà ní àrọ́wọ́tó láti ọ̀dọ̀ àwọn olùtajà wa tàbí tí wọ́n ntúmọ̀ lọ́wọ́ ni wọ́n wà nínú àtòkọ tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí. Nígbà tí àkọlé àwọn ìwé náà bá yí padà sí ojú òpó ẹ̀rọ ayélujára, a ó mú yín lọ sí àwọn ojú ewé tí ó ní àwọn àfikún àlàyé nípa àwọn ìwé ní èdè Yoruba nípa títẹ̀ sórí wọn.
Nítorí náà, láti bẹ̀rẹ̀ àtòkọ àwọn ìwé náà ní èdè Yoruba:
ẸNI TÍ A KÒ FI ÀÀYÈ GBÀ
Ìtàn Apanilẹ́rín Ti Ìdílé Jòkújòkú Kan Ní Sáà Kan
(The Disallowed)
—
Áwọn Ipele ti Megan Alágbára
Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!
(The Psychic Megan Series)
—