Ìtàn Apanilẹ́rín Ti Ìdílé Jòkújòkú Kan Ní Sáà Kan
láti ọ̀wọ́
Owen Jones
Ìtumọ̀ láti ọwọ́
Sola Agboola
ISBN e-book: 9788835416753
Heng Lee nsin ewúrẹ́ lórí àwọn òkè tí ó nasẹ̀ ní àríwá ìlà oòrùn Chiang Rai ní àríwá Thailand, tí ó súnmọ́ ẹnu-bodè Laos tímọ́-tímọ́. Ó jẹ́ ìlú tí ó wọnú ara wọn tímọ́-tímọ́ níbi tí gbogbo ènìyàn ti mọ ara wọn.
Lójijì ni Heng bẹ̀rẹ̀ àìsàn, ṣùgbọ́n kò ṣàìsàn débi pé kò lè kó àwọn ewúrẹ́ jáde, títí di ọjọ́ kan tí ó ní láti rí aláwò ní agbègbè, nítorí pé ó ti bẹ̀rẹ̀ síí dákú. Kò sí àwọn oníṣègùn òyìnbó ní agbègbè náà, Aláwo náà sì ti nṣe dáradára fún èyí tí ó pọ̀jù nínú àwọn ènìyàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
Aláwo náà mú àwọn nnkan kan ó sì sọ pé àwọn kíndìnrín Heng ti kọṣẹ́ nítorí náà ó sì ní àkókò kúkúrú láti lò láyé. Ìlàkàkà náà ntẹ̀ síwájú láti gba ẹ̀mí Heng là, ṣùgbọ́n àwọn agbára míràn wà lẹ́nu iṣẹ́ bákan náà. Kínni yóò ṣẹlẹ̀ sí Heng, ìdílé rẹ àti gbogbo ìyókù ará ìlú náà, tí ó bá gba ìmọ̀ràn Aláwo náà?
Tektime Audiobook